ByAsejere
Gomina Babajide Sanwo-Olu ti seleri ati fowosowopo pelu awon ileefowopamo, atawon olokoowo to wa nipinle naa, lati le sise won lona to rorun julo.
Sanwo-Olu soro yii nigba to gbalejo awon loga-loga nileefowopamo meta, iyen United Bank for Africa Plc, UBA; Ecobank Nigeria Plc, ati Optimus Bank. Awon banki meteeta wonyi ni won wa sile re to wa ni Marina lonii lati se baba keepe.
Ogbeni Oliver Alawuba lo saaju awon osise UBA, nigba ti Ogbeni Mobolaji Lawal saaju awon osise Ecobank, bee ni Omowe Ademola Odeyemi saaju awon osise banki Optimus.
Nigba to n ki won kaabo, Sanwo-Olu ran awon osise banki naa leti pe oun ko ti i pari saa akoko, o si ku ojo mokandinlogoji. O ni, pelu iwonba ojo yooku yii, o si lawon ise akanse toun maa yonda fun awon olugbe Eko. Awon ileewe, bee la si ni awon ileri taa se fun awon araalu taa fee mu se.
“Ko si aye ere rara, leyin eto idibo o lawon ise akanse to ye ka se, ka yonda fawon araalu. Ise si po fun wa, ohun ti iyen tunmo si ni pe a gbodo je kawon araalu ni igbagbo ninu wa.”
Bee lo si tun ro awon onileefowopamo naa ki won dide lotun lati ran awon araalu lowo pelu ififunni, paapaa awon agbegbe tileese won sodo si.
Ogbeni Oliver Alawuba to je oga agba ileefowopamo UBA ki Sanwo-Olu ku oriire ti bo se bori eleekeji, o ni aseyori naa to si gomina, nitori o sise fun un.
No comments:
Post a Comment